Mark 8:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà pẹlu mi, wọn kò ní ohun tí wọn yóo jẹ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ãnu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn kò si li ohun ti nwọn o jẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí fún wọn pé, “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàni wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ.