Mark 8:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà Jesu tún fi ọwọ́ kàn án lójú. Ọkunrin náà tẹjú mọ́ àwọn nǹkan tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ojú rẹ̀ sì bọ̀ sípò, ó wá rí gbogbo nǹkan kedere, títí kan ohun tí ó jìnnà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin eyini o si tún fi ọwọ́ kàn a loju, o si mu ki o wòke: o si sàn, o si ri gbogbo enia gbangba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, Jésù tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere.