Mark 8:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere, yóo gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi ati nitori ihinrere, on na ni yio gbà a là.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìyìn rere, òun náà ni yóò gbà á là.