Mark 9:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tún wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, àwọn kan wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun tí yóo dé pẹlu agbára.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹlomiran wà ninu awọn ti o duro nihinyi, ti kì yio tọ́ iku wò, titi nwọn o fi ri ti ijọba Ọlọrun yio fi de pẹlu agbara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún wọn pé, “Lóòtọ́ ni mo wí fún un yín àwọn mìíràn wa nínú àwọn tó dúró níhìnín yìí, tí kì yóò tọ́ ikú wò, títi yóò fi rí ìjọba Ọlọ́run tí yóò fi dé pẹ̀lú agbára.”