Mark 9:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá mú un lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ẹ̀mí burúkú yìí rí Jesu, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yí nílẹ̀, ó ń yọ ìfòòfó lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si mu u wá sọdọ rẹ̀: nigbati o si ri i, lojukanna ẹmi nã nà a tantan; o si ṣubu lulẹ o si nfi ara yilẹ o si nyọ ifofó li ẹnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan-náà ẹ̀mi náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lulẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófóò lẹ́nu.