Mark 9:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé Kapanaumu, tí wọ́n wọ inú ilé, ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ̀ ń bá ara yín sọ lọ́nà?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wá si Kapernaumu: nigbati o si wà ninu ile o bi wọn lẽre, wipe, Kili ohun ti ẹnyin mba ara nyin jiyan si li ọ̀na?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n dé sí Kapanámù. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tan nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí?”