Mark 9:38 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Johanu wí fún un pé, “Olùkọ́ni, a rí ẹnìkan tí ó ń fi orúkọ rẹ lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ṣugbọn a gbìyànjú láti dá a lẹ́kun, nítorí kì í ṣe ara wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Johanu si da a lohùn, o wipe, Olukọni, awa ri ẹnikan nfi orukọ rẹ lé awọn ẹmi èṣu jade, on kò si tọ̀ wa lẹhin: awa si da a lẹkun, nitoriti ko tọ̀ wa lẹhin:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Jòhánù, sọ fún un ní ọjọ́ kan pé, “Olùkọ́, àwá rí ọkùnrin kan, tí ń fi orúkọ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí àìmọ̀ jáde, ṣùgbọ́n a sọ fún un pé kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí kì í ṣe ọ̀kan nínú ẹgbẹ́ wa.”