Mark 9:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́ kọsẹ̀, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á gbé e sọ sinu òkun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikẹni ti o ba si mu ki ọkan ninu awọn kekeke wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o sàn fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si sọ ọ sinu omi okun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n ti ẹnikẹ́ni bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọ kékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ sìnà nínú ìgbàgbọ́ rẹ́, ó sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn ni ọ̀run, kí a sì sọ ọ́ sínú òkun.