Matthew 11:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọmọ-Eniyan dé, ó ń jẹ, ó ń mu. Wọ́n ní, ‘Ẹ kò rí ọkunrin yìí, oníjẹkújẹ ati ọ̀mùtí, ọ̀rẹ́ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.’ Ṣugbọn àyọrísí iṣẹ́ Ọlọrun fihàn pé ọgbọ́n rẹ̀ tọ̀nà.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ-enia wá, o njẹ, o si nmu, nwọn wipe, Wò o, ọjẹun, ati ọmuti, ọrẹ́ awọn agbowode ati awọn ẹlẹṣẹ. Ṣugbọn a dare fun ọgbọ́n lati ọdọ awọn ọmọ rẹ̀ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ ènìyàn wá bá a yín jẹun, ó sì bá yin mu, wọ́n wí pé, ọ̀jẹun àti ọ̀mùtì; ọ̀rẹ́ àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀, ṣùgbọ́n a dá ọgbọ́n láre nípa ìṣe rẹ̀.”