Matthew 11:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “O gbé! Korasini. Ìwọ náà sì gbé! Bẹtisaida. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Tire ati ní Sidoni ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe láàrin yín ni, wọn ìbá ti ronupiwada tipẹ́tipẹ́, tàwọn ti aṣọ ọ̀fọ̀ lára ati eérú lórí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egbé ni fun iwọ, Korasini! egbé ni fun iwọ, Betsaida! ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu nyin ni Tire on Sidoni, nwọn iba ti ronupiwada lailai ninu aṣọ ọ̀fọ ati ninu ẽru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí pé, “Ègbé ni fún ìwọ Kórásínì, ègbé ni fún ìwọ Bẹtisáídà! Ìbá ṣe pé a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a se nínú yín ní Tírè àti Sídónì, àwọn ènìyàn wọn ìbá ti ronúpìwàdà tipẹ́ nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú.