Matthew 11:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ati ìwọ, Kapanaumu, o rò pé a óo gbé ọ ga dé ọ̀run ni? Rárá o. Ní ọ̀gbun jíjìn ni a óo sọ ọ́ sí! Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ní Sodomu ni a ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe ninu rẹ ni, ìbá wà títí di òní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iwọ Kapernaumu, a o ha gbé ọ ga soke ọrun? a o rẹ̀ ọ silẹ si Ipo-oku: nitori ibaṣepe a ti ṣe iṣẹ agbara ti a ṣe ninu rẹ ninu Sodomu, on iba wà titi di oni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti ìwọ Kápánámù, a ó ha gbé ọ ga sókè ọ̀run?, Rárá a ó rẹ̀ ọ́ sílẹ̀ sí ipò òkú. Nítorí, ìbá ṣe pé a ti ṣe iṣẹ́ ìyanu tí a ṣe nínú rẹ ní Sódómù, òun ìbá wà títí di òní.