Matthew 12:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní àkókò náà Jesu ń la oko ọkà kan kọjá ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu. Ebi ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń jẹ ẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
LAKOKÒ na ni Jesu là ãrin oko ọkà lọ li ọjọ isimi; ebi si npa awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, nwọn si bẹ̀rẹ si ima ya ipẹ́ ọkà, nwọn si njẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò náà ni Jésù ń la àárin oko ọkà kan lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ebi sì ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i ya orí ọkà, wọ́n sì ń jẹ ẹ́.