Matthew 12:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá bi wọ́n báyìí pé, “Ta ni ninu yín tí yóo ní aguntan kan, bí ọ̀kan náà bá jìn sí kòtò ní Ọjọ́ Ìsinmi, tí kò ní fà á jáde?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, ọkunrin wo ni iba ṣe ninu nyin, ti o li agutan kan, bi o ba si bọ́ sinu ihò li ọjọ isimi, ti ki yio dì i mu, ki o si fà a soke?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó dá wọn lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ wí pé bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ní àgùntàn kan ṣoṣo, tí ó sì bọ́ sínú kòtò ní ọjọ́ ìsinmi, tí kì yóò dì í mú, kí ó sì fà á jáde.