Matthew 12:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Wo ọmọ mi tí mo yàn, àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi yọ̀ mọ́ Èmi óo fi Ẹ̀mí mi sí i lára, yóo kéde ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wo iranṣẹ mi, ẹniti mo yàn; ayanfẹ mi, ẹniti inu mi dùn si gidigidi: Emi o fi ẹmí mi fun u, yio si fi idajọ hàn fun awọn keferi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ wo ìránṣẹ mi ẹni tí mo yàn. Àyànfẹ́ mi ni ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi; èmi yóò fi ẹ̀mí mi fún un. Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ orílẹ̀-èdè gbogbo.