Matthew 12:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu tí ó ní ẹ̀mí èṣù; ẹ̀mí èṣù yìí ti fọ́ ọ lójú, ó sì mú kí ó yadi. Jesu bá wò ó sàn; ọkunrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì ríran.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li a gbé ọkunrin kan ti o li ẹmi èṣu, ti o fọju, ti o si yadi, wá sọdọ rẹ̀; o si mu u larada, ti afọju ati odi na sọ̀rọ ti o si riran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹmí-èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jésù sì mú un lára dá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran.