Matthew 12:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìdí nìyí tí mo fi sọ fun yín pé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati gbogbo ìsọ̀rọ̀ òdì ni a óo dárí rẹ̀ ji eniyan; ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ni mo wi fun nyin, gbogbo irú ẹ̀ṣẹ-kẹṣẹ ati ọrọ-odi li a o darijì enia; ṣugbọn ọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, on li a ki yio darijì enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀ òdì ni a yóò dárí rẹ̀ ji ènìyàn, ṣùgbọ́n ìsọ̀rọ̀-òdì-sí ẹ̀mí mímọ́ kò ní ìdáríjì.