Matthew 12:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ọmọ-Eniyan yóo rí ìdáríjì. Ṣugbọn ẹni tí ó bá sọ̀rọ̀ tí kò dára sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní rí ìdáríjì láyé yìí ati ní ayé tí ń bọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba nsọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a ki yio dari rẹ̀ jì i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dárí jì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí jì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀.