Matthew 12:42 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọbabinrin láti ilẹ̀ gúsù yóo ko ìran yìí lójú ní ìdájọ́ yóo sì dá a lẹ́bi. Nítorí ó wá láti ọ̀nà jíjìn láti gbọ́ ọgbọ́n Solomoni. Ẹ wò ó, ẹni tí ó ju Solomoni lọ ló wà níhìn-ín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọbabirin gusù yio dide pẹlu iran yi li ọjọ idajọ, yio si da a lẹbi: nitori o ti ikangun aiye wá igbọ́ ọgbọ́n Solomoni; si wò o, ẹniti o pọ̀ ju Solomoni lọ mbẹ nihinyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọbabìnrin gúsù yóò sì dìde ní ọjọ́ ìdájọ́ sí ìran yìí yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí tí ó wá láti ilẹ̀ ìkangun ayé láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n láti ẹnu Sólóḿonì. Ṣùgbọ́n báyìí ẹni tí ó pọ̀ jù Sólómónì ń bẹ níhìn-ín yìí.