Matthew 13:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ẹni tí ó bá ní nǹkan, òun ni a óo tún fún sí i, kí ó lè ní ànító ati àníṣẹ́kù. Ẹni tí kò bá sì ní, a óo gba ìwọ̀nba díẹ̀ tí ó ní lọ́wọ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ẹnikẹni ti o ba ni, on li a ó fifun, on o si ni li ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti ko ba si ni, lọwọ rẹ̀ li a o si gbà eyi na ti o ni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹnikẹ́ni tí ó ní, òun ni a ó fún sí i, yóò sì ní lọ́pọ̀lọpọ̀. Ṣùgbọ́n lọ́wọ́ ẹni tí kò ní, ni a ó ti gbà èyí kékeré tí ó ní náà.