Matthew 13:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Báyìí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aisaya ṣe ṣẹ sí wọn lára, nígbà tí ó sọ pé. ‘Ní ti gbígbọ́, ẹ óo gbọ́, ṣugbọn kò ní ye yín; ní ti pé kí ẹ ríran, ẹ óo wò títí, ṣugbọn ẹ kò ní rí nǹkankan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si ara wọn ni ọrọ̀ Isaiah wolí si ti ṣẹ, ti o wipe, Ni gbigbọ́ ẹnyin ó gbọ́, kì yio si yé nyin; ati riri ẹnyin o ri, ẹnyin kì yio si moye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sí ara wọn ni a ti mú àṣọtẹ́lẹ̀ wòlíì Àìsáyà ṣẹ: “ ‘Ní gbígbọ́ ẹ̀yin yóò gbọ́ ṣùgbọn kì yóò sì yé yín; ní rírí ẹ̀yin yóò rí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò sì mòye.