Matthew 13:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkàn àwọn eniyan yìí ti le, etí wọn ti di, wọ́n sì ti di ojú wọn. Kí wọn má baà fi ojú wọn ríran, kí wọn má baà fi etí wọn gbọ́ràn, kí wọn má baà mòye, kí wọn má baà yipada, kí n wá gbà wọ́n là.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo ọ̀ran igbọ́, oju wọn ni nwọn si dì; nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi àiya wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki emi ki o má ba mu wọn larada.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́ etí wọn sì wúwo láti gbọ́ ojú wọn ni wọ́n sì dì nítorí kí àwọn má ba à fi ojú wọn rí kí wọ́n má ba à fi ètí wọn gbọ́ kí wọn má ba à fi àyà wọn mọ̀ òge, kí wọn má ba à yí padà, kí èmi ba à le mú wọn lára dá.’