Matthew 13:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀pọ̀ àwọn wolii ati àwọn olódodo dàníyàn láti rí àwọn nǹkan tí ẹ̀ ń rí, ṣugbọn wọn kò rí wọn; wọ́n fẹ́ gbọ́ àwọn ohun tí ẹ̀ ń gbọ́ ṣugbọn wọn kò gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, ọ̀pọlọpọ wolĩ ati olododo ni nfẹ ri ohun ti ẹnyin ri, nwọn kò si ri wọn; nwọn si nfẹ gbọ́ ohun ti ẹ gbọ́, nwọn ko si gbọ́ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì àti ènìyàn Ọlọ́run ti fẹ́ rí ohun tí ẹ̀yin ti rí, ki wọ́n sì gbọ́ ohun tí ẹ ti gbọ́, ṣùgbọ́n kò ṣe é ṣe fún wọn.