Matthew 13:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ó kéré jùlọ ninu gbogbo irúgbìn, sibẹ nígbà tí ó bá dàgbà, a tóbi ju gbogbo ewébẹ̀ lọ. A di igi, tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run óo wá ṣe ìtẹ́ wọn lára ẹ̀ka rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eyiti o kére jù gbogbo irugbin lọ; ṣugbọn nigbati o dàgba, o tobi jù gbogbo ewebẹ lọ, o si di igi, tobẹ ti awọn ẹiyẹ oju ọrun si wá, nwọn ngbé ori ẹ̀ka rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrin èṣo rẹ̀, ṣíbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ìbùgbé.”