Matthew 13:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn. Ó ní, “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obinrin kan mú, tí ó pò mọ́ òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun ńláńlá mẹta títí gbogbo rẹ̀ fi wú sókè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Owe miran li o pa fun wọn pe, Ijọba ọrun dabi iwukara, ti obinrin kan mu, ti o sin sinu oṣuwọn iyẹfun mẹta, titi gbogbo rẹ̀ fi di wiwu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí yíìsìtì tí obìnrin kan mú tí ó pò mọ́ ìyẹ̀fun (ìyẹ̀fun) púpọ̀ títí tí gbogbo rẹ fi di wíwú.”