Matthew 13:35 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí ọ̀rọ̀ tí wolii ti sọ lè ṣẹ, nígbà tí ó sọ pé, “Bí òwe bí òwe ni ọ̀rọ̀ mi yóo jẹ́. N óo sọ àwọn ohun tí ó ti wà ní àṣírí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki eyiti a ti ẹnu woli sọ ki o ba le ṣẹ, wipe, Emi ó yà ẹnu mi li owe; emi ó sọ nkan wọnni jade ti o ti fi ara pamọ́ lati iṣẹ̀dalẹ aiye wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ọ̀rọ̀ tí a ti ẹnu àwọn wòlíì sọ lé wá sí ìmúsẹ pé: “Èmi yóò ya ẹnu mi láti fi òwe sọ̀rọ̀. Èmi yóò sọ àwọn ohun tí ó farasin láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá.”