Matthew 13:44 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Báyìí ni ìjọba ọ̀run rí. Ó dàbí ìṣúra iyebíye kan tí wọ́n fi pamọ́ ninu ilẹ̀. Nígbà tí ẹnìkan rí i, ó bò ó mọ́lẹ̀, ó lọ tayọ̀tayọ̀, ó ta ohun gbogbo tí ó ní, ó bá ra ilẹ̀ náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ijọba ọrun si dabi iṣura ti a fi pamọ́ sinu oko, ti ọkunrin kan ri, ti o pa a mọ́; nitori ayọ̀ rẹ̀, o lọ, o si ta gbogbo ohun ti o ni, o si rà oko na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà.