Matthew 13:54 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó dé ìlú baba rẹ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn lọ́nà tí ó yà wọ́n lẹ́nu. Wọ́n ń sọ pé, “Níbo ni eléyìí ti ní irú ọgbọ́n yìí? Níbo ni ó ti rí agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu báyìí?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si de ilu on tikalarẹ, o kọ́ wọn ninu sinagogu wọn, tobẹ̃ ti ẹnu yà gbogbo wọn, nwọn si wipe, Nibo li ọkunrin yi ti mu ọgbọ́n yi ati iṣẹ agbara wọnyi wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Ṣínágọ́gù, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá?