Matthew 14:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan jókòó lórí koríko. Ó mú burẹdi marun-un náà ati ẹja meji; ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́, ó bá bù wọ́n, ó kó wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá pín in fún àwọn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si paṣẹ ki ijọ enia joko lori koriko, o si mu iṣu akara marun ati ẹja meji na; nigbati o gbé oju soke ọrun, o sure, o si bù u, o fi akara na fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si fifun ijọ enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn náà, ó wí fún àwọn ènìyàn kí wọ́n jókòó lórí koríko. Lẹ́yìn náà, ó mú ìṣù àkàrà márùn-un àti ẹja méjì. Ó gbé ojú rẹ̀ sí ọ̀run. Ó béèrè ìbùkún Ọlọ́run lórí oúnjẹ náà, Ó sì bù ú, ó sì fi àkàrà náà fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti pín in fún àwọn ènìyàn.