Matthew 14:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wí fún àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni èyí. Òun ni ó jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí rẹ̀ nìyí tí ó fi ní agbára láti lè ṣe iṣẹ́ ìyanu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li eyi; o jinde kuro ninu okú; nitorina ni iṣẹ agbara ṣe hàn lara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ó wí fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, “Dájúdájú Jòhánù onítẹ́bọmi ni èyí, ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ìdí nìyí tí ó fi ní agbára láti ṣiṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí.”