Matthew 14:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí wọn sá lè fi ọwọ́ kan etí ẹ̀wù rẹ̀. Gbogbo àwọn tí wọ́n fi ọwọ́ kàn án ni ó mú lára dá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki nwọn ki o sá le fi ọwọ́ kàn iṣẹti aṣọ rẹ̀: ìwọn gbogbo awọn ti o si fi ọwọ́ kàn a, di alara dida ṣáṣá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn aláìsàn bẹ̀ ẹ́ pé kí ó gba àwọn láyè láti fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí ó ṣe bẹ́ẹ̀ sì rí ìwòsàn.