Matthew 16:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu si dahùn o si wi fun u pe, Alabukun-fun ni iwọ Simoni Ọmọ Jona: ki iṣe ẹran ara ati ẹ̀jẹ li o sá fi eyi hàn ọ, ṣugbọn Baba mi ti mbẹ li ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì wí fún un pé, “Alábùnkún-fún ni ìwọ Símónì ọmọ Jónà, nítorí ènìyàn kọ́ ló fi èyí hàn bí kò se Baba mi tí ó ń bẹ ní ọ̀run.