Matthew 16:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí máa fihan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé dandan ni kí òun lọ sí Jerusalẹmu, kí òun jìyà pupọ lọ́wọ́ àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin; ati pé kí wọ́n pa òun, ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí òun dìde.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati igbana lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ si ifihàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bi on ko ti le ṣailọ si Jerusalemu, lati jẹ ọ̀pọ ìya lọwọ awọn àgbagbà ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ki a si pa on, ati ni ijọ kẹta, ki o si jinde.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìgbà yìí lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí iṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerúsálémù láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn, olórí àwọn àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, pé wọn yóò pa òun, àti pé òun yóò jí dìde sí ààyè ní ọjọ́ kẹ́ta.