Matthew 16:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jésù wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.