Matthew 16:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní òwúrọ̀ ẹ̀wẹ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ìjì yóo jà lónìí nítorí pé ojú ọ̀run pupa, ó sì ṣú.’ Ẹ mọ ohun tí àmì ojú ọ̀run jẹ́, ṣugbọn ẹ kò mọ àwọn àmì àkókò yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati li owurọ̀ ẹnyin a wipe, Ọjọ kì yio dara loni, nitori ti oju ọrun pọ́n, o si ṣú dẹ̀dẹ. A! ẹnyin agabagebe, ẹnyin le mọ̀ àmi oju ọrun; ṣugbọn ẹnyin ko le mọ̀ àmi akokò wọnyi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òwúrọ̀, ‘Èyin yóò wí pé ọjọ́ kì yóò dára lónìí, nítorí ti ojú ọ̀run pọ́n, ó sì ṣú dẹ̀dẹ̀,’ ẹ̀yin àgàbàgebè, ẹ̀yin le sọ àmì ojú ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò le mọ àmì àwọn àkókò wọ̀nyí.