Matthew 17:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Kí ló dé? A máa san án.” Nígbà tí ó dé ilé, Jesu ló ṣáájú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní, “Kí ni o rò, Simoni? Lọ́wọ́ àwọn ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó-orí tabi owó-odè? Lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ ni tabi lọ́wọ́ àlejò?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O wipe, Bẹ̃ni. Nigbati o si wọ̀ ile, Jesu ṣiwaju rẹ̀, o bi i pe, Simoni, iwọ ti rò o si? lọwọ tali awọn ọba aiye ima gbà owodè? lọwọ awọn ọmọ wọn, tabi lọwọ awọn alejò?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pétérù sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.” Nígbà tí Pétérù wọ ilé láti bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jésù ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jésù bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Símónì? Ǹjẹ́ àwọn ọba ń gba owó-orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?”