Matthew 17:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Sibẹ kí á má baà jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún wọn, lọ sí etí òkun, ju ìwọ̀ sí omi; ẹja kinni tí o bá fà sókè, mú un, ya ẹnu rẹ̀, o óo rí owó fadaka kan níbẹ̀. Mú un kí o fi fún wọ́n fún owó tèmi ati tìrẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ki a má bã bí wọn ninu, iwọ lọ si okun, ki o si sọ ìwọ si omi, ki o si mu ẹja ti o ba kọ́ fà soke; nigbati iwọ ba si yà a li ẹnu, iwọ o ri ṣekeli kan nibẹ̀: on ni ki o mu, ki o si fifun wọn fun temi ati tirẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú’ Nítorí náà, ẹ lọ sí etí òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó-orí tèmi àti tirẹ̀.”