Matthew 17:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má sọ ohun tí ẹ rí fún ẹnikẹ́ni títí a óo fi jí Ọmọ-Eniyan dìde kúrò ninu òkú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, Jesu kìlọ fun wọn pe, Ẹ máṣe sọ̀rọ iran na fun ẹnikan, titi Ọmọ-enia yio fi tun jinde kuro ninu okú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n sì ti ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè, Jésù pàṣẹ fún wọn pé “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí ọmọ-ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú”