Matthew 18:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Kí ni ẹ rò? Bí ọkunrin kan bá ní ọgọrun-un aguntan, tí ọ̀kan ninu wọn bá sọnù, ǹjẹ́ ọkunrin náà kò ní fi aguntan mọkandinlọgọrun-un yòókù sílẹ̀ lórí òkè, kí ó lọ wá èyí tí ó sọnù?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin ti rò o si? bi ọkunrin kan ba ni ọgọrun agutan, bi ọkan nù ninu wọn, kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ̀, kì yio lọ sori òke lọ iwá eyi ti o nù bi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kí ni ẹ̀yin rò? Bí ọkùnrin kan bá ni ọgọ́rùn-ún àgùntàn, tí ẹyọ kan nínú wọn sì sọnù, ṣé òun kì yóò fi mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99) ìyókù sílẹ̀ sórí òkè láti lọ wá ẹyọ kan tó nù náà bí?