Matthew 18:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ ohun ìkọsẹ̀ fún ọ̀kan ninu àwọn kéékèèké wọnyi tí ó gbà mí gbọ́, ó sàn fún un kí á so ọlọ ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí á sọ ọ́ sinu ibú òkun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ọkan ninu awọn kekere wọnyi ti o gbà mi gbọ́ kọsẹ̀, o ya fun u ki a so ọlọ nla mọ́ ọ li ọrùn, ki a si rì i si ibú omi okun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó bá mú ọ̀kan nínú àwọn ọmọkékeré wọ̀nyí tí ó gbà mí gbọ́ sìnà, yóò sàn fún un kí a so òkúta ńlá mọ́ ọn lọ́rùn, kí a sì rì í sí ìsàlẹ̀ ibú omi òkun.