Matthew 18:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Bí ọwọ́ tabi ẹsẹ̀ rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí o wọ inú ìyè pẹlu àbùkù ọwọ́ tabi ti ẹsẹ̀, jù pé kí o ní ọwọ́ meji tabi ẹsẹ̀ meji kí á sọ ọ́ sinu iná àjóòkú lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ọwọ́ rẹ tabi ẹsẹ rẹ ba si mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sàn fun ọ ki o ṣe akewọ, tabí akesẹ lọ sinu ìye, jù ki o li ọwọ́ meji tabi ẹsẹ meji, ki a gbé ọ jù sinu iná ainipẹkun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹṣẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé.