Matthew 19:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí àwọn ẹlòmíràn jẹ́ akúra kí á tó bí wọn, eniyan sọ àwọn mìíràn di akúra; àwọn ẹlòmíràn sì sọ ara wọn di akúra nítorí ti ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gba èyí, kí ó gbà á.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iwẹfa miran mbẹ, ti a bí bẹ̃ lati inu iya wọn wá: awọn iwẹfa miran mbẹ ti awọn araiye sọ di iwẹfa: awọn iwẹfa si wà, awọn ti o sọ ara wọn di iwẹfa nitori ijọba ọrun. Ẹniti o ba le gbà a, ki o gbà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn mìíràn jẹ́ akúra nítorí bẹ́ẹ̀ nía bí wọn, àwọn mìíràn ń bẹ tí ènìyàn sọ wọn di bẹ́ẹ̀; àwọn mìíràn kọ̀ láti gbé ìyàwó nítorí ìjọba ọ̀run. Ẹni tí ó bá lè gbà á kí ó gbà á.”