Matthew 2:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọ́n ti wọlé, wọ́n rí ọmọ náà pẹlu Maria ìyá rẹ̀, wọ́n kúnlẹ̀, wọ́n sì júbà rẹ̀. Wọ́n ṣí àpótí ìṣúra wọn, wọ́n fún un ní ẹ̀bùn: wúrà, turari ati òjíá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si wọ̀ ile, nwọn ri ọmọ-ọwọ na pẹlu Maria iya rẹ̀, nwọn wolẹ, nwọn si foribalẹ fun u: nigbati nwọn si tú iṣura wọn, nwọn ta a lọrẹ wura, ati turari, ati ojia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n tí wọ inú ilé náà, wọn rí ọmọ ọwọ́ náà pẹ̀lú Màríà ìyá rẹ̀, wọ́n wólẹ̀, wọ́n forí balẹ̀ fún un. Nígbà náà ni wọ́n tú ẹrù wọn, wọ́n sì ta Jésù lọ́rẹ: wúrà, tùràrí àti òjíà.