Matthew 2:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí àwọn amòye ti pada lọ, angẹli Oluwa kan fara han Josẹfu ní ojú àlá, ó sọ fún un pé, “Dìde, gbé ọmọ náà ati ìyá rẹ̀, kí o sálọ sí Ijipti, kí o sì wà níbẹ̀ títí di ìgbà tí mo bá sọ fún ọ, nítorí Hẹrọdu yóo máa wá ọmọ náà láti pa á.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati nwọn si ti lọ, kiyesi i, angẹli Oluwa yọ si Josefu li oju alá, o wipe, Dide gbé ọmọ-ọwọ na pẹlu iya rẹ̀, ki o si sálọ si Egipti, ki iwọ ki o si gbé ibẹ̀ titi emi o fi sọ fun ọ; nitori Herodu yio wá ọmọ-ọwọ na lati pa a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí wọn ti lọ, ańgẹ́lì Olúwa fara hàn Jósẹ́fù ní ojú àlá pé, “Dìde, gbé ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀, kí ó sì sá lọ sí Éjíbítì. Dúró níbẹ̀ títítí èmi yóò fi sọ fún ọ, nítorí Hẹ́rọ̀dù yóò wá ọ̀nà láti pa ọmọ-ọwọ́ náà.”