Matthew 2:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“A gbọ́ ohùn kan ní Rama, ẹkún ati ọ̀fọ̀ gidi. Rakẹli ń sunkún nítorí àwọn ọmọ rẹ̀; ó kọ̀, kò gba ìpẹ̀, nítorí wọn kò sí mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni Rama ni a gbọ́ ohùn, ohùnréré, ati ẹkún, ati ọ̀fọ nla, Rakeli nsọkun awọn ọmọ rẹ̀ ko gbipẹ, nitoriti nwọn ko si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“A gbọ́ ohùn kan ní Rámà, Ohùn réré ẹkún àti ọ̀fọ̀ ńlá Rákélì ń sọkùn àwọn ọmọ rẹ̀ Ó kọ̀ láti gbìpẹ̀ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀ tí kò sí mọ́.”