Matthew 2:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si wá, o joko ni ilu kan ti a npè ni Nasareti; ki eyi ti a ti sọ li ẹnu woli ki o le ṣẹ, pe, A o pè e ni ará Nasareti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ó sì lọ í gbé ní ìlú tí a pè ní Násárẹ́tì. Nígbà náà ni èyí tí a sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì wá sí ìmúṣẹ: “A ó pè é ní ará Násárẹ́tì.”