Matthew 2:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
‘Àní ìwọ Bẹtilẹhẹmu ilẹ̀ Juda, o kì í ṣe ìlú tí ó rẹ̀yìn jùlọ ninu àwọn olú-ìlú Juda. Nítorí láti inú rẹ ni aṣiwaju kan yóo ti jáde, tí yóo jẹ́ olùṣọ́-aguntan fún Israẹli, eniyan mi.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ Betlehemu ni ilẹ Judea, iwọ kò kere julọ ninu awọn ọmọ alade Juda, nitori lati inu rẹ ni Bãlẹ kan yio ti jade, ti yio ṣe itọju Israeli awọn enia mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ní ilẹ̀ Jùdíà, ìwọ kò kéré jù láàrin àwọn ọmọ aládé Jùdíà; nítorí láti inú rẹ ni Baálẹ̀ kan yóò ti jáde, Ẹni ti yóò ṣe àkóso lórí Ísírẹ́lì, àwọn ènìyàn mi.’ ”