Matthew 20:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn tí wọn kọ́kọ́ dé ibi iṣẹ́ dé, wọ́n rò pé wọn yóo gbà ju owó fadaka kọ̀ọ̀kan lọ. Ṣugbọn owó fadaka kọ̀ọ̀kan ni àwọn náà gbà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati awọn ti o ti ṣaju de, nwọn ṣebi awọn o gbà jù bẹ̃ lọ; olukuluku wọn si gbà owo idẹ kọkan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣíṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó ti wọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan.