Matthew 20:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn ọlọ́gbà àjàrà náà dá ọ̀kan ninu wọn lóhùn pé, ‘Arakunrin, n kò rẹ́ ọ jẹ. Àdéhùn owó fadaka kan ni mo bá ọ ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si da ọkan ninu wọn lohùn pe, Ọrẹ́, emi ko ṣìṣe si ọ: iwọ ki o ba mi pinnu rẹ̀ si owo idẹ kan li õjọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀rẹ́, kò sí aburú nínú nǹkan tí èmi ṣe sí yín. Kì í ha ṣe pé ẹ̀yin gbà láti ṣiṣẹ́ fún owó dínárì kan.