Matthew 20:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó sọ fún wọn pé, “Lódodo ẹ óo mu ninu ife mi, ṣugbọn láti jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi ati ní ọwọ́ òsì mi kò sí ní ìkáwọ́ mi láti fi fún ẹnikẹ́ni, ipò wọnyi wà fún àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún láti ọ̀dọ̀ Baba mi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun wọn pe, Lõtọ li ẹnyin o mu ninu ago mi, ati ninu baptismu ti a o fi baptisi mi li a o si fi baptisi nyin; ṣugbọn lati joko li ọwọ́ ọtún ati li ọwọ́ òsi mi, ki iṣe ti emi lati fi funni, bikoṣepe fun kìki awọn ẹniti a ti pèse rẹ̀ silẹ fun lati ọdọ Baba mi wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú aago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jòkòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè àyè wọ́n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.”