Matthew 20:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn eniyan bá wọn wí pé kí wọ́n panu mọ́. Ṣugbọn ńṣe ni wọ́n túbọ̀ ń kígbe pé, “Oluwa ṣàánú wa, ọmọ Dafidi.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn enia si ba wọn wi, nitori ki nwọn ki o ba le pa ẹnu wọn mọ́: ṣugbọn nwọn kigbe jù bẹ̃ lọ, wipe, Oluwa, iwọ Ọmọ Dafidi, ṣãnu fun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sóke sí i. “Olúwa, ọmọ Dáfídì, ṣàánú fún wa!”